Video & Song Lyrics ::: Ko S’ohun T’o Le – Sola Allyson

Deal Score0
Deal Score0

Seasoned Indigenous Nigerian Gospel Artist, Sola Allyson has released the official music video to “Ko S’ohun T’o Le” off her 9th released album; “Isodotun.”

The visual for Ko S’ohun T’o Le by Sola Allyson comes weeks after she dropped the visual of her song Ife A Dale which featured Yoruba movie stars Dele Odule, Iya Rainbow, Lateef Adedimeji and Bimpe Oyebade.

Ko S’ohun T’o Le video was shot & directed by Director Swag.

Watch Video Below; 

https://www.youtube.com/watch?v=FLZI99Z9RqI

Lyrics: Ko S’ohun T’o Le By Sola Allyson

Baba wa ti n be l’orun
Owo ni f’ooko Re
Ife Tire ni ko se
Lori oro aye wa
Baba wa ti n be l’orun
Owo ni f’ooko Re

Ko s’ohun to le
F’Olohun lati se
Ko s’ohun to le
F’Olohun lati se
O lana s’okun
Jabesi d’oloriire
Igba lo yato
Ko s’ohun to le
F’Olohun lati se

Ko si o…

Ko s’ohun to le (Omo ma gbagbe, ko s’ohun to le)
F’Olohun lati se (Iri a dojo, ojo a ro, ile a gba imisi)
Ko s’ohun to le (Ibukun a wa, ma gbagbe o)
F’Olohun lati se
O lana s’okun (Okun di ‘yangbe ile, ohun ta a ro pe o le sele)
Jabesi d’oloriire
Igba lo yato (Omo)
Ko s’ohun to le (Ko si, ko si, omo ma gbagbe o)
F’Olohun lati se

Igbagbo la nilo fun ‘se iyanu Re (Baba Nla)
Ireti la nilo fun ‘se iyanu Re (Baba Iyanu)
Ife la nilo fun ‘se iyanu Re (Ko le se)
Ko s’ohun to le
F’Olohun lati se

Igbagbo la nilo fun ‘se iyanu Re (Baba Nla)
Ireti la nilo fun ‘se iyanu Re (Baba Iyanu)
Ife la nilo fun ‘se iyanu Re (Ko le se)
Ko s’ohun to le (Omo ma gbagbe, omo ma gbagbe o)
F’Olohun lati se

Igbagbo la nilo fun ‘se iyanu Re (Baba Nla)
Ireti la nilo fun ‘se iyanu Re (Baba Iyanu)
Ife la nilo fun ‘se iyanu Re (Ko le se)
Ko s’ohun to le (Omo ma gbagbe o, omo ma gbagbe o)
F’Olohun lati se

Ko s’ohun to le (Se o gbagbe se, opo la ri ka)
F’Olohun lati se (Opo ni o tie l’akoole, opo la n ri…)
Ko s’ohun to le (sugbon ta o k’obi ara si…)
F’Olohun lati se (Ko si, ko si ooo)
O lana s’okun (Nigba t’aye ro p’o tan, nigba t’aye ro p’o tan o)
Jabesi d’oloriire (Emi naa mo ni ijerisi temi)
Igba lo yato (Ko si, ko si o)
Ko s’ohun to le (Omo ma gbagbe)
F’Olohun lati se

Baba wa ti n be l’orun
Owo ni f’ooko Re (Oni iyonu julo, Baba)
Ife Tire ni ko se
Lori oro aye wa
Baba wa ti n be l’orun (Alagbara julo)
Owo ni f’ooko Re

Bi mo ba f’oju okan wo okun to pinya, eru a ba mi o
Ara mi a segiri wipe Alagbara ni Baba wa
Igba lo yato, omo eniyan, o je lo gbe je
Tete ko se temi lo n beere, A a se ‘yanu
Bi mo ba f’oju okan wo okun to pinya, eru a ba mi o
Ara mi a segiri wipe Alagbara ni Baba wa
Igba lo yato, omo eniyan, o je lo gbe je (Ma gbagbe o, ma gbagbe o)
Tete ko se temi lo n beere, A a se ‘yanu

A a se ‘yanu
A a se ‘yanu o, A a se ‘yanu
A a se ‘yanu
Ni se lo kan dabi pe o le gan
O dabi pe o le
Oniyonu ni Baba wa
A a mu aanu wa
A a se ‘yanu, omo ma gbagbe
A a se ‘yanu
Tete ko se temi lo n beere o
A a se ‘yanu
(Ko s’ohun ti o le se, awa ni k’a t’ero ara wa pa, k’a ye ‘ra wa wo, k’a bo sinu ife Oluwa gangan)
A a se ‘yanu (Eni ikosile wa, nise lo kan dabi pe o le gan, A a se ‘yanu o)
A a se ‘yanu
Tete ko se temi lo n beere o
A a se ‘yanu

Oluwa mo gba o gbo
Ko sohun t’o o le se
Mo gbagbo pe iyanu a sele
K’o ri fun mi gege bi oro Re
Emi yoo sa ma se ife Re
Oluwa, k’o ri fun mi gege bi oro Re
Amin

Hits: 0

NectesGM
Show full profile

NectesGM

NgospelMedia.Net Author Contributor Team.

NgospelMedia.Com
Logo